4
Àwọn ẹ̀kọ́ fun Timotiu
1 Nísinsin yìí, èmi ń tẹnumọ́ ọ́ pé ní ìgbà ìkẹyìn àwọn mìíràn yóò kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọn yóò máa fiyèsí àwọn ẹ̀mí tí ń tannijẹ, àti ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù.
2 Nípa àgàbàgebè àwọn tí ń ṣèké, àwọn tí ọkàn tìkára wọn dàbí èyí tí a fi irin gbígbóná jó.
3 Àwọn tí ń dánilẹ́kun láti gbéyàwó tiwọn si ń pàṣẹ láti ka èèwọ̀ oúnjẹ ti Ọlọ́run ti dá fún ìtẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ọpẹ́ àwọn onígbàgbọ́ àti àwọn ti ó mọ òtítọ́.
4 Nítorí gbogbo ohun ti Ọlọ́run dá ni ó dára, kò sí ọkàn tí ó yẹ kí a kọ̀, bí a bá fi ọpẹ́ gbà á.
5 Nítorí tí a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àdúrà yà sí mímọ́.
6 Bí ìwọ bá ń rán àwọn ará létí nǹkan wọ̀nyí, ìwọ ó jẹ́ ìránṣẹ́ rere ti Kristi Jesu, tí a fi ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ àti ẹ̀kọ́ rere bọ́, èyí ti ìwọ ti ń tẹ̀lé.
7 Ṣùgbọ́n kọ ọ̀rọ̀ asán àti ìtàn àwọn àgbà obìnrin, sì máa tọ́ ara rẹ sí ìwà-bí-Ọlọ́run.
8 Nítorí ṣíṣe eré-ìdárayá ni èrè fún ohun díẹ̀, ṣùgbọ́n ìwà-bí-Ọlọ́run ni èrè fún ohun gbogbo, ó ní ìlérí ti ìgbé ayé ìsinsin yìí àti ti èyí tí ń bọ̀.
9 Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, ó sì yẹ fún ìtẹ́wọ́gbà gbogbo.
10 Nítorí fún èyí ni àwa ń ṣe làálàá tí a sì ń jìjàkadì, nítorí àwa ní ìrètí nínú Ọlọ́run alààyè, ẹni tí í ṣe Olùgbàlà gbogbo ènìyàn, pẹ̀lúpẹ̀lú ti àwọn ti ó gbàgbọ́.
11 Nǹkan wọ̀nyí ni kí ó máa paláṣẹ kí ó máa kọ́ni.
12 Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni gan ìgbà èwe rẹ; ṣùgbọ́n kì ìwọ jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn tí ó gbàgbọ́, nínú ọ̀rọ̀, nínú ìwà híhù, nínú ìfẹ́, nínú ẹ̀mí, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́.
13 Títí èmi ó fi dé, máa fiyèsí kíkàwé àti ìgbaniníyànjú àti ìkọ́ni.
14 Má ṣe àìnání ẹ̀bùn tí ń bẹ lára rẹ, èyí tí a fi fún ọ nípa ìsọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ìgbọ́wọ́lé àwọn alàgbà.
15 Máa fiyèsí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá; kí ìlọsíwájú rẹ lè hàn gbangba fún gbogbo ènìyàn.
16 Máa ṣe ìtọ́jú ará rẹ àti ẹ̀kọ́ rẹ; máa dúró láìyẹsẹ̀ nínú nǹkan wọ̀nyí; nítorí ní ṣíṣe èyí, ìwọ ó gba ara rẹ àti tí àwọn ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ là.