Saamu 60
Fún adarí orin. Tí ohùn “Lílì ti Májẹ̀mú.” Miktamu ti Dafidi. Fún ìkọ́ni. Nígbà tí ó bá Aramu-Naharaimu àti Siria-Soba jà, àti nígbà tí Joabu yípadà tí ó sì pa ẹgbẹ̀rún méjìlá àwọn ará Edomu ní àfonífojì Iyọ̀.
1 Ìwọ ti kọ̀ wá sílẹ̀,
Ọlọ́run, ìwọ ti tú wa ká,
ìwọ ti bínú nísinsin yìí, tún ara rẹ yípadà sí wa.
2 Ìwọ ti mú ilẹ̀ wárìrì, ìwọ ti fọ́ ọ;
mú fífọ́ rẹ̀ bọ̀ sípò, nítorí tí ó mì.
3 Ìwọ ti fi ìgbà ewu han àwọn ènìyàn rẹ;
ìwọ fún wa ní wáìnì tí ó máa ń ta wá gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n.
4 Àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, ní ìwọ fi ọ̀págun fún
kí a lè fihàn nítorí òtítọ́.
Sela.
5 Fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbà wá, kí o sì ràn wá lọ́wọ́,
kí a lè gba àwọn tí o fẹ́ là.
6 Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀:
“Ní ayọ̀, èmi ó pọ Ṣekemu jáde
èmi ó sì wọ́n àfonífojì Sukkoti.
7 Tèmi ni Gileadi, tèmi sì ni Manase;
Efraimu ni àṣíborí mi,
Juda sì ni ọ̀pá àṣẹ mi.
8 Moabu ní ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi,
lórí Edomu ní mo bọ́ bàtà mi sí;
lórí Filistia ni mo kígbe ayọ̀.”
9 Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi nì?
Ta ni yóò tọ́ mí lọ sí Edomu?
10 Kì í ha ń ṣe ìwọ, Ọlọ́run, tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀
tí o kò sì bá ogun wa jáde mọ́?
11 Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ lórí àwọn ọ̀tá,
nítorí asán ni ìrànlọ́wọ́ ènìyàn.
12 Nípa Ọlọ́run ni a óò ní ìṣẹ́gun,
yóò sì tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.