Saamu 48
Orin. Saamu ti àwọn ọmọ Kora.
Ẹni ńlá ní Olúwa, tí ó sì yẹ láti máa yìn
ní ìlú Ọlọ́run wa, lórí òkè mímọ́ rẹ̀.
 
+Ó dára nínú ipò ìtẹ́ rẹ̀,
ayọ̀ gbogbo ayé,
òkè Sioni, ní ìhà àríwá
ní ìlú ọba ńlá.
Ọlọ́run wà nínú ààbò ààfin rẹ̀;
ó fi ara rẹ̀ hàn láti jẹ́ odi alágbára.
 
Nígbà tí àwọn ọba kógun jọ pọ̀,
wọ́n jùmọ̀ ń kọjá lọ.
Wọn rí i, bẹ́ẹ̀ ni ẹnu sì yà wọ́n,
a yọ wọ́n lẹ́nu, wọ́n yára lọ.
Ẹ̀rù sì bà wọ́n níbẹ̀,
ìrora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó wà nínú ìrọbí.
Ìwọ bà wọ́n jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọkọ̀ orí omi Tarṣiṣi,
wọ́n fọ́nká láti ọwọ́ ìjì ìlà-oòrùn.
 
Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́,
bẹ́ẹ̀ ni àwa rí,
ní inú Olúwa àwọn ọmọ-ogun
ní ìlú Ọlọ́run wa,
Ọlọ́run jẹ́ kí ó wà ní abẹ́ ààbò títí láéláé.
Sela.
 
Láàrín tẹmpili rẹ, Ọlọ́run,
àwa ti ń sọ ti ìṣeun ìfẹ́ rẹ.
10 Gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ Ọlọ́run,
ìyìn rẹ̀ dé òpin ayé,
ọwọ́ ọ̀tún rẹ kún fún òdodo.
11 Jẹ́ kí òkè Sioni kí ó yọ̀
kí inú àwọn ọmọbìnrin Juda kí ó dùn
nítorí ìdájọ́ rẹ.
 
12 Rìn Sioni kiri lọ yíká rẹ̀,
ka ilé ìṣọ́ rẹ̀.
13 Kíyèsi odi rẹ̀,
kíyèsi àwọn ààfin rẹ̀
kí ẹ̀yin lè máa wí fún ìran tí ń bọ̀.
 
14 Nítorí Ọlọ́run yìí Ọlọ́run wà ní títí ayé,
Òun ni yóò ṣe amọ̀nà wa títí dè òpin ayé.
+ Saamu 48:2 Mt 5.35.