19
Ó sàn kí ènìyàn jẹ́ tálákà tí ìrìn rẹ̀ kò lábùkù
ju aláìgbọ́n tí ètè rẹ̀ jẹ́ àyídáyidà.
 
Kò dára láti ní ìtara láìní ìmọ̀,
tàbí kí ènìyàn kánjú kí ó sì ṣìnà.
 
Ìwà òmùgọ̀ ènìyàn fúnra rẹ̀ a pa ẹ̀mí rẹ̀ run;
síbẹ̀ ọkàn rẹ̀ yóò máa bínú sí Olúwa.
 
Ọrọ̀ máa ń fa ọ̀rẹ́ púpọ̀;
ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ tálákà tún kọ̀ ọ́ sílẹ̀.
 
Ajẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà,
ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde kò ní lọ lọ́fẹ̀ẹ́.
 
Ọ̀pọ̀ ń wá ojúrere olórí;
gbogbo ènìyàn sì ni ọ̀rẹ́ ẹni tí ó lawọ́.
 
Gbogbo ará ilé e tálákà ni ó pa á tì,
mélòó mélòó ni ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ń sá fún un!
Bí ó tilẹ̀ ń lé wọn kiri pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀,
kò tilẹ̀ le rí wọn rárá.
 
Ẹni tí ó gba ọgbọ́n fẹ́ràn ọkàn ara rẹ̀;
ẹni tí ó bá káràmáṣìkí òye yóò gbèrú.
 
Ajẹ́rìí èké kì yóò lọ láìjìyà
ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde yóò parun.
 
10 Kò yẹ aláìgbọ́n láti máa gbé nínú ọláńlá,
mélòó mélòó bí ó ti burú tó fún ẹrú láti jẹ ọba lórí ọmọ-aládé.
 
11 Ọgbọ́n ènìyàn a máa fún un ní sùúrù;
fún ògo rẹ̀ ni láti fojú fo àṣìṣe dá.
 
12 Ìbínú ọba dàbí kíké e kìnnìún,
ṣùgbọ́n ojúrere rẹ̀ dàbí ìrì lára koríko.
 
13 Aṣiwèrè ọmọ jẹ́ ìparun baba rẹ̀,
aya tí ó máa ń jà sì dàbí ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀ òjò.
 
14 A máa ń jogún ilé àti ọrọ̀ lọ́dọ̀ òbí,
ṣùgbọ́n aya olóye láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni.
 
15 Ọ̀lẹ ṣíṣe máa ń fa oorun sísùn fọnfọn,
ebi yóò sì máa pa ènìyàn tí ó lọ́ra.
 
16 Ẹnikẹ́ni tí ó gbọ́ ẹ̀kọ́ pa ẹnu rẹ̀ mọ́,
ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kẹ́gàn ọ̀nà rẹ̀ yóò kú.
 
17 Ẹni tí ó ṣàánú tálákà, Olúwa ní ó yá,
yóò sì pín in lérè ohun tí ó ti ṣe.
 
18 Bá ọmọ rẹ wí nítorí nínú ìyẹn ni ìrètí wà;
àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ lọ́wọ́ nínú ìparun un rẹ̀.
 
19 Ènìyàn onínú-fùfù gbọdọ̀ gba èrè ìwà rẹ̀;
bí ìwọ bá gbà á là, ìwọ yóò tún ní láti ṣe é lẹ́ẹ̀kan sí i.
 
20 Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ẹ̀kọ́,
ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín ìwọ yóò di ọlọ́gbọ́n.
 
21 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ète inú ọkàn ènìyàn,
ṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa ní ó máa ń borí.
 
22 Ohun tí ènìyàn ń fẹ́ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀;
ó sàn láti jẹ́ tálákà ju òpùrọ́ lọ.
 
23 Ìbẹ̀rù Olúwa ń mú ìyè wá;
nígbà náà ọkàn ń balẹ̀, láìsí ewu.
 
24 Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú àwo oúnjẹ;
kò tilẹ̀ ní mú u padà wá sí ẹnu rẹ̀.
 
25 Na ẹlẹ́gàn, òpè yóò sì kọ́gbọ́n;
bá olóye ènìyàn wí, yóò sì ní ìmọ̀ sí i.
 
26 Ẹni tí ó ṣìkà sí baba rẹ̀, tí ó sì lé ìyá rẹ̀ jáde
òun ni ọmọ tí ń ṣe ìtìjú, tí ó sì mú ẹ̀gàn wá.
 
27 Ọmọ mi, dẹ́kun láti tẹ́tí sí ẹ̀kọ́,
tí í mú ni ṣìnà kúrò nínú ọ̀rọ̀-ìmọ̀.
 
28 Ẹlẹ́rìí búburú fi ìdájọ́ ṣẹ̀sín,
ẹnu ènìyàn búburú sì ń gbé ibi mì.
 
29 A ti pèsè ìjìyà sílẹ̀ fún ẹlẹ́gàn;
àti pàṣán fún ẹ̀yìn àwọn aṣiwèrè.