4
Òkè Olúwa
1 Ní ọjọ́ ìkẹyìn
a ó fi òkè ilé Olúwa lélẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá,
a ó sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèké lọ,
àwọn ènìyàn yóò sì máa wọ̀ sínú rẹ̀.
2 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yóò wá,
wọn yóò sì wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá Olúwa,
àti sí ilé Ọlọ́run Jakọbu.
Òun yóò sì kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀,
kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.”
Òfin yóò jáde láti Sioni wá,
àti ọ̀rọ̀ Olúwa láti Jerusalẹmu.
3 Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ láàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn,
yóò sì parí aáwọ̀ fún orílẹ̀-èdè alágbára jíjìn réré.
Wọn yóò sì fi idà wọn rọ ohun èlò ìtulẹ̀
àti ọ̀kọ̀ wọn di dòjé
orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè mọ́,
bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.
4 Ṣùgbọ́n olúkúlùkù yóò jókòó lábẹ́ àjàrà rẹ̀
àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀,
ẹnìkan kì yóò sì dẹ́rùbà wọ́n,
nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ̀rọ̀.
5 Gbogbo àwọn ènìyàn ń rìn,
olúkúlùkù ni orúkọ ọlọ́run tirẹ̀,
ṣùgbọ́n àwa yóò máa rìn ní orúkọ Olúwa.
Ọlọ́run wa láé àti láéláé.
Èrò Olúwa
6 “Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí,
“Èmi yóò kó àwọn arọ jọ;
èmi yóò sì ṣà àwọn tí a lé kúrò ní ìlú jọ,
àti àwọn ẹni tí èmi ti pọ́n lójú.
7 Èmi yóò dá àwọn arọ sí fún èyí tókù,
èmi yóò sì sọ àwọn tí a lé kúrò ní ìlú di orílẹ̀-èdè alágbára.
Olúwa yóò sì jẹ ọba lórí wọn ní òkè ńlá Sioni
láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.
8 Ní ti ìwọ, ilé ìṣọ́ agbo àgùntàn,
odi alágbára ọmọbìnrin Sioni,
a ó mú ìjọba ìṣáájú padà bọ̀ sípò fún un yín;
ìjọba yóò sì wà sí ọ̀dọ̀ ọmọbìnrin Jerusalẹmu.”
9 Kí ni ìwọ ha ń kígbe sókè sí nísinsin yìí?
Ǹjẹ́ ìwọ kò ní ọba bí?
Àwọn ìgbìmọ̀ rẹ ṣègbé bí?
Nítorí ìrora ti dì ọ́ mú bí obìnrin tí ń rọbí.
10 Máa yí síyìn-ín sọ́hùn-ún nínú ìrora,
ìwọ obìnrin Sioni,
bí ẹni tí ń rọbí,
nítorí nísinsin yìí ìwọ yóò jáde lọ kúrò ní ìlú,
ìwọ yóò sì máa gbé inú igbó.
Ìwọ yóò lọ sí Babeli;
níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì ti rí ìgbàlà.
Níbẹ̀ ni Olúwa yóò ti rà ọ́ padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ.
11 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ọ̀pọ̀lọpọ̀ Orílẹ̀-èdè kó ara wọn jọ sí ọ.
Wọ́n sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sọ ọ́ di àìmọ́,
ẹ jẹ́ kí ojú wa kí ó wo Sioni!”
12 Ṣùgbọ́n wọn kò mọ
èrò inú Olúwa;
bẹ́ẹ̀ ni òye ìmọ̀ rẹ̀ kò yé wọn,
nítorí ó ti kó wọn jọ bí i ìtí sínú ìpakà.
13 “Dìde, kí ó sì máa pa ọkà ìwọ ọmọbìnrin Sioni,
nítorí èmi yóò sọ ìwo rẹ̀ di irin,
èmi yóò sì sọ pátákò rẹ̀ di idẹ
ìwọ yóò run ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè pátápátá.”
Èmi yóò sì ya èrè wọn sọ́tọ̀ fún Olúwa
àti ọrọ̀ wọn sí Olúwa gbogbo ayé.