61
Ọdún ojúrere Olúwa
1 Ẹ̀mí Olúwa Olódùmarè wà lára mi
nítorí Olúwa ti fi àmì òróró yàn mí
láti wàásù ìyìnrere fún àwọn tálákà.
Ó ti rán mi láti ṣe àwòtán oníròbìnújẹ́
láti kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn
àti ìtúsílẹ̀ kúrò nínú òkùnkùn fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n,
2 láti kéde ọdún ojúrere Olúwa
àti ọjọ́ ẹ̀san ti Ọlọ́run wa,
láti tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú,
3 àti láti pèsè fún àwọn tí inú wọn bàjẹ́ ní Sioni
láti dé wọn ládé ẹwà dípò eérú,
òróró ayọ̀ dípò ọ̀fọ̀,
àti aṣọ ìyìn dípò ìpòrúru ọkàn.
A ó sì pè wọ́n ní igi óákù òdodo,
irúgbìn Olúwa
láti fi ọláńlá rẹ̀ hàn.
4 Wọn yóò tún àwọn ahoro àtijọ́ kọ́
wọn yóò sì mú àwọn ibi ìparun àtijọ́-tijọ́ náà bọ̀ sípò;
wọn yóò jí àwọn ahoro ìlú náà padà
tí a ti parun láti ìrandíran sẹ́yìn.
5 Àwọn àjèjì ni yóò máa da ọ̀wọ́ ẹran rẹ;
àwọn àlejò yóò sì ṣiṣẹ́ nínú oko àti ọgbà àjàrà rẹ.
6 A ó sì máa pè yín ní àlùfáà Olúwa,
a ó pè yín ní ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa.
Ẹ ó máa jẹ nínú ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè
àti nínú ọrọ̀ wọn ni ẹ̀yin yóò máa ṣògo.
7 Dípò àbùkù wọn
àwọn ènìyàn mi yóò gba ìlọ́po méjì,
àti dípò àbùkù wọn
wọn yóò yọ̀ nínú ìní wọn;
bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì jogún ìlọ́po méjì ní ilẹ̀ wọn,
ayọ̀ ayérayé yóò sì jẹ́ tiwọn.
8 “Nítorí Èmi, Olúwa fẹ́ràn ìdájọ́ òdodo;
mo kórìíra olè jíjà àti ẹ̀ṣẹ̀.
Ní òtítọ́ mi èmi yóò sẹ̀san fún wọn
èmi yóò sì dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lú wọn.
9 A ó mọ ìrandíran wọn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè
àti àwọn ìran wọn láàrín àwọn ènìyàn.
Gbogbo àwọn tí ó bá rí wọn yóò mọ̀ pé
wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn tí Olúwa ti bùkún.”
10 Èmi yọ̀ gidigidi nínú Olúwa;
ọkàn mi yọ̀ nínú Ọlọ́run mi.
Nítorí ó ti wọ̀ mí ní aṣọ ìgbàlà
ó sì ṣe mí lọ́ṣọ̀ọ́ nínú aṣọ òdodo;
gẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ti ṣe orí rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ bí àlùfáà,
àti bí ìyàwó ṣe ń ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́.
11 Gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ti í mú irúgbìn jáde
àti bí ọgbà ṣe ń mú irúgbìn dàgbà,
bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Olódùmarè yóò ṣe mú òdodo àti ìyìn
kí ó ru sókè níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè.