57
1 Olódodo ṣègbé
kò sí ẹnìkan tí ó rò ó lọ́kàn ara rẹ̀;
a mú àwọn ẹni mímọ́ lọ,
kò sì ṣí ẹni tó yé
pé a ti mú àwọn olódodo lọ
láti yọ wọ́n kúrò nínú ibi.
2 Gbogbo àwọn tí ń rìn déédé
ń wọ inú àlàáfíà;
wọ́n rí ìsinmi bí wọ́n ti ń sùn nínú ikú.
3 “Ṣùgbọ́n ẹ súnmọ́ ìhìn-ín, ẹ̀yin ọmọ aláfọ̀ṣẹ,
ẹ̀yin irú-ọmọ panṣágà àti àgbèrè!
4 Ta ni ó fi ń ṣẹlẹ́yà?
Ta ni o ń yọ ṣùtì sí
tí o sì yọ ahọ́n síta?
Ẹ̀yin kì í ha ṣe ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn bí,
àti ìran àwọn òpùrọ́?
5 Ẹ gbinájẹ fún ìṣekúṣe láàrín igi óákù
àti lábẹ́ gbogbo igi tí ń gbilẹ̀;
ẹ fi àwọn ọmọ yín rú ẹbọ nínú kòtò jíjìn
àti lábẹ́ àwọn pàlàpálá òkúta.
6 Àwọn ère tí ó wà ní àárín òkúta dídán
wọ́n n nì, nínú kòtò jíjìn ni ìpín in yín;
àwọ̀n ni ìpín in yín.
Bẹ́ẹ̀ ni, sí wọn ni ẹ ti ta ọrẹ ohun mímu yín sílẹ̀
àti láti ta ọrẹ ìyẹ̀fun.
Nítorí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó yẹ
kí n dáwọ́ dúró?
7 Ìwọ ti ṣe ibùsùn rẹ lórí òkè gíga tí ó rẹwà;
níbẹ̀ ni ẹ lọ láti lọ ṣe ìrúbọ yín.
8 Lẹ́yìn àwọn ìlẹ̀kùn yín àti òpó ìlẹ̀kùn yín
níbẹ̀ ni ẹ fi àwọn àmì òrìṣà yín sí.
Ní kíkọ̀ mí sílẹ̀, ẹ ṣí ibùsùn yín sílẹ̀,
ẹ gun orí rẹ̀ lọ, ẹ sì ṣí i sílẹ̀ gbagada;
ẹ ṣe àdéhùn pẹ̀lú àwọn tí ẹ fẹ́ràn ibùsùn wọn,
ẹ̀yin sì ń wo ìhòhò wọn.
9 Ẹ̀yin lọ sí Moleki pẹ̀lú òróró olifi
ẹ sì fi kún òórùn dídùn yín.
Ẹ rán ikọ̀ yín lọ jìnnà réré;
ẹ sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú!
10 Àwọn ọ̀nà yín gbogbo ti mú àárẹ̀ ba á yín,
ṣùgbọ́n ẹ kò ní sọ pé, ‘Kò sí ìrètí mọ́?’
Ẹ rí okun kún agbára yín,
nípa bẹ́ẹ̀ òòyì kò kọ́ ọ yín.
11 “Ta ni ó ń pá yín láyà tí ń bà yín lẹ́rù
tí ẹ fi ń ṣèké sí mi,
àti tí ẹ̀yin kò fi rántí mi
tàbí kí ẹ rò yí nínú ọkàn yín?
Ǹjẹ́ kì í ṣe nítorí dídákẹ́ jẹ́ẹ́ mi fún ìgbà pípẹ́
tí ẹ̀yin kò fi bẹ̀rù mi?
12 Èmi yóò ṣí òdodo yín páyà àti iṣẹ́ yín,
wọn kì yóò sì ṣe yín ní àǹfààní.
13 Nígbà tí ẹ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́
ẹ jẹ́ kí àkójọ àwọn ère yín gbà yín!
Atẹ́gùn yóò gbá gbogbo wọn lọ,
èémí lásán làsàn ni yóò gbá wọn lọ.
Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fi mí ṣe ààbò rẹ̀
ni yóò jogún ilẹ̀ náà
yóò sì jogún òkè mímọ́ mi.”
Ìtùnú fún àwọn oníròbìnújẹ́
14 A ó sì sọ wí pé:
“Tún mọ, tún mọ, tún ọ̀nà náà ṣe!
Ẹ mú àwọn ohun ìkọ̀sẹ̀ kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn mi.”
15 Nítorí èyí ni ohun tí Ẹni gíga àti ọlọ́lá jùlọ wí
ẹni tí ó wà títí láé, tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́:
“Mo ń gbé ní ibi gíga àti ibi mímọ́,
ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹni n nì tí ó ní ìròbìnújẹ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀,
láti sọ ẹ̀mí onírẹ̀lẹ̀ náà jí
àti láti sọ ẹ̀mí oníròbìnújẹ́ n nì jí.
16 Èmi kì yóò fẹ̀sùn kan ni títí láé,
tàbí kí n máa bínú sá á,
nítorí nígbà náà ni ọkàn ènìyàn yóò
rẹ̀wẹ̀sì níwájú mi
èémí ènìyàn tí mo ti dá.
17 Inú bí mi nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀kánjúwà rẹ̀;
mo fìyà jẹ ẹ́, mo sì fojú mi pamọ́ ní ìbínú;
síbẹ̀, ó tẹ̀síwájú nínú tinú-mi-ni n ó ṣe ọ̀nà rẹ̀.
18 Èmi ti rí ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, ṣùgbọ́n Èmi yóò wò ó sàn;
Èmi yóò tọ́ ọ ṣọ́nà n ó sì mú ìtùnú tọ̀ ọ́ wá,
19 ní dídá ìyìn sí ètè àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ní Israẹli.
Àlàáfíà, àlàáfíà fún àwọn tí ó wà lókèèrè àti nítòsí,”
ni Olúwa wí, “Àti pé, Èmi yóò wo wọ́n sàn.”
20 Ṣùgbọ́n àwọn ìkà dàbí i ríru Òkun
tí kò le è sinmi,
tí ìgbì rẹ̀ ń rú pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ àti ẹrọ̀fọ̀ sókè.
21 “Kò sí àlàáfíà fún àwọn ìkà,” ni Ọlọ́run mi wí.