17
Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ ní ti Damasku
1 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Damasku:
“Kíyèsi i, Damasku kò ní jẹ́ ìlú mọ́
ṣùgbọ́n yóò padà di ààtàn.
2 Àwọn ìlú Aroeri ni a ó kọ̀sílẹ̀
fún àwọn agbo ẹran tí yóò máa sùn síbẹ̀,
láìsí ẹni tí yóò dẹ́rùbà wọ́n.
3 Ìlú olódi ni yóò pòórá kúrò ní Efraimu,
àti agbára ọba kúrò ní Damasku;
àwọn àṣẹ́kù Aramu yóò dá
gẹ́gẹ́ bí ògo ti àwọn Israẹli,”
ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
4 “Ní ọjọ́ náà ni ògo Jakọbu yóò sá;
ọ̀rá ara rẹ̀ yóò ṣòfò dànù.
5 Yóò sì dàbí ìgbà tí olùkórè kó àwọn
irúgbìn tí ó dúró jọ
tí ó sì ń kórè irúgbìn pẹ̀lú apá rẹ̀—
àti gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ènìyàn pa ọkà ní àfonífojì ti Refaimu.
6 Síbẹ̀síbẹ̀ irúgbìn díẹ̀ yóò ṣẹ́kù,
gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a gbọn igi olifi,
tí èso olifi méjì tàbí mẹ́ta ṣẹ́kù
sórí ẹ̀ka tí ó ga jùlọ,
mẹ́rin tàbí márùn-ún lórí ẹ̀ka tí ó so jù,”
ni Olúwa wí, àní Ọlọ́run Israẹli.
7 Ní ọjọ́ náà, àwọn ènìyàn yóò gbójú sókè sí Ẹlẹ́dàá wọn,
wọn yóò sì síjú wo Ẹni Mímọ́ Israẹli.
8 Wọn kò ní wo àwọn pẹpẹ mọ́,
èyí tí í ṣe iṣẹ́ ọwọ́ wọn,
wọn kò sì ní kọbi ara sí ère Aṣerah mọ́
tàbí pẹpẹ tùràrí tí ìka ọwọ́ wọn ti ṣe.
9 Ní ọjọ́ náà àwọn ìlú alágbára rẹ̀, yóò dàbí ẹ̀ka ìkọ̀sílẹ̀, àti ẹ̀ka téńté òkè tí wọ́n fi sílẹ̀ nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Gbogbo wọn yóò sì di ahoro.
10 Nítorí ìwọ ti gbàgbé Ọlọ́run ìgbàlà rẹ;
tí ìwọ kò sì náání àpáta ìgbàlà rẹ̀,
nítorí náà ni ìwọ ti gbin ọ̀gbìn dáradára
ìwọ sì tọ́ àjèjì ẹ̀ka sínú rẹ̀.
11 Nítorí náà, bí ẹ tilẹ̀ mú àṣàyàn igi tí ẹ sì gbin àjàrà tí ó ti òkèrè wá,
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ tí ẹ kó wọn jáde ẹ mú wọn hù jáde,
àti ní òwúrọ̀ tí ẹ gbìn wọ́n
ẹ mú kí wọ́n rúdí,
síbẹ̀síbẹ̀ ìkórè kò ní mú nǹkan wá
ní ọjọ́ ààrùn àti ìrora tí kò gbóògùn.
12 Kíyèsi i, ìrunú àwọn orílẹ̀-èdè—
wọ́n ń runú bí ìgbì Òkun!
Kíyèsi i, rògbòdìyàn tí ogunlọ́gọ̀ ènìyàn
wọ́n bú ramúramù gẹ́gẹ́ bí ariwo odò ńlá!
13 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń bú
ramúramù gẹ́gẹ́ bí ìrúmi odò,
nígbà tí ó bá wọn wí wọ́n sálọ jìnnà réré,
a tì wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò ní orí òkè,
àti gẹ́gẹ́ bí ewéko níwájú ìjì líle.
14 Ní aginjù, ìpayà òjijì!
Kí ó tó di òwúrọ̀, a ò rí wọn mọ́!
Èyí ni ìpín àwọn tí ó jí wa lẹ́rù,
àti ìpín àwọn tí ó fi ogun kó wa.