15
Àsọtẹ́lẹ̀ lòdì sí Moabu
1 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Moabu,
a pa Ari run ní Moabu,
òru kan ní a pa á run!
A pa Kiri run ní Moabu,
òru kan ní a pa á run!
2 Diboni gòkè lọ sí tẹmpili rẹ̀,
sí àwọn ibi gíga rẹ̀ láti sọkún,
Moabu pohùnréré lórí Nebo àti Medeba.
Gbogbo orí ni a fá
gbogbo irùngbọ̀n ni a gé dànù.
3 Wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀ ní ojú òpópónà,
ní àwọn òrùlé àti àwọn gbàgede ìlú.
Wọ́n pohùnréré,
wọ́n dọ̀bálẹ̀ pẹ̀lú ẹkún.
4 Heṣboni àti Eleale ké sóde,
ohùn wọn ni a gbọ́ títí fi dé Jahasi.
Nítorí náà ni àwọn ọmọ-ogun Moabu ṣe kígbe
tí ọkàn wọn sì rẹ̀wẹ̀sì.
5 Ọkàn mi kígbe sókè lórí Moabu;
àwọn ìsáǹsá rẹ sálà títí dé Soari,
títí fi dé Eglati-Ṣeliṣi.
Wọ́n gòkè lọ títí dé Luhiti
wọ́n ń sọkún bí wọ́n ti ń lọ,
ní òpópónà tí ó lọ sí Horonaimu
wọ́n ń pohùnréré ìparun wọn.
6 Gbogbo omi Nimrimu ni ó ti gbẹ
àwọn koríko sì ti gbẹ,
gbogbo ewéko ti tán
ewé tútù kankan kò sí mọ́.
7 Báyìí gbogbo ọrọ̀ tí wọ́n ti ní tí wọ́n sì tò jọ
wọ́n ti kó wọn kọjá lọ lórí i gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ odò Poplari.
8 Gbohùngbohùn ń gba igbe wọn dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ Moabu;
ìpohùnréré wọn lọ títí dé Eglaimu,
igbe ẹkún wọn ni a gbọ́ títí dé kànga Elimu.
9 Omi Dimoni kún fún ẹ̀jẹ̀,
síbẹ̀ èmi ó tún mu ohun tí ó jù báyìí lọ wá sórí Dimoni—
kìnnìún kan wá sórí àwọn ìsáǹsá Moabu
àti lórí àwọn tí ó tún ṣẹ́kù sórí ilẹ̀ náà.