12
1 Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ
ní ọjọ́ èwe rẹ,
nígbà tí ọjọ́ ibi kò tí ì dé
àti tí ọdún kò tí ì ní súnmọ́ etílé, nígbà tí ìwọ yóò wí pé,
“Èmi kò ní ìdùnnú nínú wọn,”
2 kí oòrùn àti ìmọ́lẹ̀
àti òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tó ṣókùnkùn,
àti kí àwọsánmọ̀ tó padà lẹ́yìn òjò;
3 nígbà tí olùṣọ́ ilé yóò wárìrì
tí àwọn ọkùnrin alágbára yóò tẹríba,
nígbà tí àwọn tí ó ń lọ dákẹ́ nítorí pé wọn kò pọ̀,
tí àwọn tí ń wo òde láti ojú fèrèsé yóò ṣókùnkùn;
4 nígbà tí ìlẹ̀kùn sí ìgboro yóò tì
tí ariwo ọlọ yóò dákẹ́;
nígbà tí àwọn ènìyàn yóò dìde sí ariwo àwọn ẹyẹ
ṣùgbọ́n gbogbo orin wọn yóò máa lọ ilẹ̀.
5 Nígbà tí ènìyàn yóò bẹ̀rù ibi gíga
àti ti ìfarapa ní ìgboro;
nígbà tí igi almondi yóò tanná
àti tí ẹlẹ́ǹgà yóò wọ́ ara rẹ̀ lọ
tí ìfẹ́ kò sì ní ru sókè mọ́
nígbà náà ni ènìyàn yóò lọ ilé rẹ́ ayérayé
tí àwọn aṣọ̀fọ̀ yóò máa rìn kiri ìgboro.
6 Rántí rẹ̀ kí okùn fàdákà tó já,
tàbí kí ọpọ́n wúrà tó fọ́;
kí iṣà tó fọ́ níbi ìsun,
tàbí kí àyíká kẹ̀kẹ́ kí ó tó kán níbi kànga.
7 Tí erùpẹ̀ yóò sì padà sí ilẹ̀ ibi tí ó ti wà,
tí ẹ̀mí yóò sì padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tí ó fi í fún ni.
8 “Asán! Asán!” ni Oniwaasu wí.
“Gbogbo rẹ̀ asán ni!”
Òpin gbogbo ọrọ̀
9 Kì í ṣe wí pé Oniwaasu jẹ́ ọlọ́gbọ́n nìkan, ṣùgbọ́n ó tún kọ́ àwọn ènìyàn ní ìmọ̀. Ó rò ó dáradára ó sì ṣe àwárí, ó sì gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwe kalẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ.
10 Oniwaasu wádìí láti rí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó tọ̀nà, ohun tí ó kọ sì dúró ṣinṣin ó sì jẹ́ òtítọ́.
11 Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹ̀gún, àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ wọn sì dàbí ìṣó tí a kàn pọ̀ dáradára, tí olùṣọ́-àgùntàn kan fi fún ni.
12 Àti síwájú láti inú èyí, ọmọ mi, gba ìmọ̀ràn.
Nínú ìwé púpọ̀, òpin kò sí, ìwé kíkà púpọ̀ a máa mú ara ṣàárẹ̀.
13 Nísinsin yìí,
òpin gbogbo ọ̀rọ̀ tí a gbọ́ ni pé,
bẹ̀rù Ọlọ́run, kí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́,
nítorí èyí ni ojúṣe gbogbo ènìyàn.
14 Nítorí Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́ olúkúlùkù iṣẹ́
àti ohun ìkọ̀kọ̀,
kì bá à ṣe rere kì bá à ṣe búburú.